Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Lílò Àkókò Rẹ Fún ỌlọrunÀpẹrẹ

Using Your Time for God

Ọjọ́ 1 nínú 4

Lílo Àkókò Rẹ Ní Ọ̀nà Tó Ní Ìtumọ̀

Nígbà tí mo wà l'ọ́mọdé ní ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn èèyàn a máa bi mí lọ́pọ́ ìgbà wípé, "Kí ni kókó ẹ̀kọ́ tí o fẹ́ràn jùlọ?" Mi ò sì kí ń ba èsì mi tì. Nínú kí n dáhùn wípé àkókò "oúnjẹ" tàbí "eré." Ìdáhùn mi ṣe àfihàn àwọn ǹkan tí mo fẹ́ràn láti máa ṣe. Mo fẹ́ràn eré ju iṣẹ́ lọ. Kódà, àwọn ìrònú mi nípa ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn a máa jẹyọ bí mo bá ti ń ṣeré lọ́nà ilé-ìwé.


Mo máa ń bèrè lọ́wọ́ ara mi, èrèdí iṣẹ́ ṣíṣe fún ọjọ́ márùn-ún láàárín ọ̀sẹ̀ lórí ǹkan tí n kò fẹ́ràn pẹ̀lú ìrètí àǹfààní àti ṣeré ní òpin ọ̀sẹ̀. Ní ojojúmọ́ ni mo máa ń dé ọgbà ilé-ìwé mi ní wákàtí kan kí ẹ̀kọ́ tó bẹ̀rẹ̀—kìí ṣe pé ìwé kíkà dùn mọ́ mi tọ́bẹ̀, bí kò ṣe láti ní àǹfààní eré ṣíṣe fún wákàtí kan gbáko kí ago àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ tó lù. Fún mi, ríra ìgbà padà túmọ̀ sí pípa rí gbogbo iṣẹ́ ní kọ́mọ́kọ́mọ́ láti lè ní àyè tótó fún eré.


Ó ti wá wá hàn sí mi báyìí wípé nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń rọ àwọn ènìyàn rẹ̀ láti ṣe "(ìràpadà) ìgbà, nítorí búburú ni àwọn ọjọ́" (Éfésù 5:16), àwọn ìmẹ́lẹ́ mi nípa eré ṣíṣe kọ́ ni ó ní lọ́kàn. Ohun tó ń gbìyànjú láti ṣe ni pípé àwọn ènìyàn láti lo àkókò wọn fún iṣẹ́ nínú ìjọba Kristi.


Coram Deo: Wíwà ní sàkání Ọlọ́run

Ǹjẹ́ o tilẹ̀ ń lo àkókò rẹ lọ́nà tó ní ìtumọ̀ fún ìjọba Ọlọ́run?


Copyright © Ligonier Ministries. Lo àǹfààní yìí láti rí ìwé ọ̀fẹ́ gbà lọ́wọ́ R.C. Sproul ní Ligonier.org/freeresource.


Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Using Your Time for God

Ẹkọ bíbélì ọlọjọ merin lati ọwọ R.C. Sproul lórí lílo àkókò wà fún Ọlọrun. Ẹkọ bíbélì ikankàn npè wà láti máa gbé ní iwájú Ọlọrun, labẹ aṣẹ Ọlọrun, sí ògo Ọlọrun.

A fẹ lati dupẹ lọwọ Ligonier Ministries fun ìpèsè ètò yìí. Fún aláayè lẹkunrẹrẹ, jọwọ lọsi Ligonier.org/youversion

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa