Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Ọjọ́ Mẹ́fà lóríi Orúkọ Ọlọ́runÀpẹrẹ

Six Days Of The Names Of God

Ọjọ́ 1 nínú 6

Ọjọ́ Kínní: EL EMUNAH – ỌLỌ́RUN OLÓÒTÍTỌ́


A má ń fẹ́ rí ara wa bíi ẹni tó jẹ́ olódodo. A n dé ibi iṣẹ́ lákòókò (ní ọ̀pọ̀ ìgbà) a sì ń ṣe iṣẹ́ wa bó ṣe tọ àti bó ṣe yẹ. À ń fi ààyè sílẹ̀ fún ẹbí àti ọ̀rẹ́. À ń ṣe oríṣiríṣi nínú ìjọ, à ń darapọ̀ mọ́ ìgbìmọ̀, à ń forúkọ sílẹ̀ láti farajìn ṣiṣẹ́. Ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí a gbìyànjú tó láti jẹ́ olóòtítọ́, a jẹ́ aláìpé. Ó dájú pé, a ó pa ìpàdé kan jẹ tàbí kí á má lè yọjú sí ìdíje eré e bọ́ólù ọmọ tàbí kí á gbàgbé à ti ṣe iṣẹ́ tí a yàn wá níbi tí a ti fara jìn.


Nítorí ó ṣòro fún wa láti jẹ́ ènìyàn tí olóòtítọ́, ó fini lọ́kàn ba lẹ̀ láti mọ̀ wípé Ọlọ́run Olóòtítọ́ là ń sìn. Orúkọ Rẹ̀ ni El Emunah tó túmọ̀ sí “Ọlọ́run tó jẹ́ Olóòtítọ́,” a leè jẹ́rìí Rẹ̀ pé yíò farahàn, Yíò sì sán ṣòkòtò Rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ nínú ayé wa. Ǹjẹ́ Ó ún pa ìlérí Rẹ̀ mọ́ bí? Bẹẹ ni. Ǹjẹ́ Ó ún gbọ àdúrà? Bẹẹ n. Ǹjẹ́ Ó wà pẹ̀lú wa títí láé? Bẹẹ ni.


Nkàn a má ṣẹlẹ̀ sí wa tí ó lè mú kí á má fi gbogbo ara jẹ́ olóòtítọ́ sí àwọn ẹlòmíràn. Nítorí ènìyàn tí a jẹ́, a ma ń dán wa wò láti yàn lóríi ìpele ìlọ́ra ayé ara ẹni, ìpele ìmọtaraẹni nìkan ati wọ̀bìà. Ní kúkúrú, a ò lè jẹ́ pípé ní gbogbo ìgbà. Nígbàtí a bá kùnà, Ọlọ́run Kìí kùnà. Yíò fi pẹ̀lẹ́ tọwa padà sí iṣẹ́ tí Ó ti yàn fún wa ní pàtó láti ṣe—iṣẹ́ jíjẹ́ olóòtítọ́ àti jíjẹ́ onígbọ̀wọ́ fún àwọn míràn. Tí a bá kọjú sí pípé Rẹ̀ ní àkókò àìpé wa, òtítọ́ Rẹ̀ yóò yí ayé wa padà.


Tí o bá ríi pé ètò wíwá ojú Ọlọ́run yí ni túmọ̀, a ṣe tán láti fún ọ ní ìwàásù àká sílẹ̀ tó dá lórí orúkọ Jehovah Jireh. Bèèrè fún ẹkùn rẹ́rẹ́ ìwàásù láti ọwọ́ Tony Evans níbí


Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Six Days Of The Names Of God

Láti inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orukọ Ọlọ́run, Ó ti fi àwòrán dí ẹ̀ hàn wá bí Òun ṣe jẹ́ àti àbùdá Rẹ̀. Ju ìwọ̀n Baba, Ọmọ, Ẹ̀mí Mímọ́ lọ, Bíbélì fi ọgọ́rin ó lé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ orúkọ Ọlọ́run hàn. Ẹ̀kọ́ yìí ṣe ìtọ́ka sí mẹ́fà àti ìtumọ̀ ...

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́, The Urban Alternative àti Tony Evans fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://tonyevans.org/

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa