Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Bibeli Fun Awon OmodeÀpẹrẹ

Bibeli Fun Awon Omode

Ọjọ́ 1 nínú 7




Tani oseda wa? Bibeli, oro Olorun, so bi iran eniyan se bere. Latetekose, Olorun da okunrin akoko osi pe oruko re ni Adamu. Olorun da Adamu lati inu erupe ile. Nigbati Olorun mi emi iye sinu Adamu, odi alaye. Ori ara re ninu ogba didara kan ti ape ni Edeni.

Ki Olorun t’oda Adamu, oda Ile aiye tokun fun ohun meremere. Leselese Olorun da awon oke ati awon ile tokun fun ewe, fulawa oloorun didun ati awon igi nla, awon eiye alawo didara ati awon kokoro oyin, eja nla inu okun ati awon igbin. Lotito, Olorun da ohun gbogbo toye.

Ni ibere ohungbogbo, ki Olorun toda ohunkohun, kosi ohun kan afi Olorun. Kosi Imole tabi okunkun. Kosi oke kosi ile. Kosi ana kosi ola. Olorun tiko ni ibere nikan lowa. Olorun sib ere ise.

Latetekose, Olorun da awon orun ati aiye.

Aiye siwa ni juujuu osi sofo. Okunkun siwa loju ibu. Olorun si wipe “Jeki imole wa”.

Imole siwa. Olorun pe imole ni ojo ati okunkun ni oru. Ati Asale ati owuro ni ojo akoko.

Ni ojo keji, Olorun mu awon omi osa, omi okun ati omi adagun bo si ipo won labe orun. Ni ojo keta, Olorun wipe, “Jeki Ile kofi ara han”. Osi ri be.

Olorun p’ase wipe ki koriko ati ewebe ati igi ati igi eleso farahan. Won si farahan. Ati asale ati owuro ni ojo keta.

Olorun da oorun, ati osupa, ati awon irawo oju orun ti enikan kolee ka. Ati asale ati owuro, ni ojo kerin.

Awon eda inu omi ati eja ati eiye ni Olorun da. Ni ojo karun Olorun da eja nla ati kekere, eiye olorungigun ati eiye kekeke. Olorun da oniruru eja lati kun inu omi ati oniruru eiye lati gbadun ile, ati okun ati ofurufu. Ati asale ati owuro ni ojo Karun.

Lehin eyi, Olorun tun wipe “Jeki ile mu oniruru eda alaye jade …” Oniruru eranko ati kokoro, ati eranko ti nrako si jade wa. Awon erin nlanla ati eran igbe. Awon obo ati oni ti nrako. Awon ekolo ati eran igbe. Awon Ologbo ati oniruru eranko igbe ni Olorun da l’ojo na. Ati asale ati owuro ni ojo kefa.

Olorun se ohun miran ni ojo kefa – Ohun ti o se pataki. Ohun gbogbo ti wa n'le fun eniyan. Ounje wa ni oko ati awon eranko ti yio sin. Olorun si so wipe, “Jeki ada eniyan li aworan ara wa. Jeki oje oluwa lori lori oungbogbo ti o wa ni ile.” OLORUN DA ENIYAN NI AWORAN RE; NI AWORAN RE L’ODA ENIYAN …

Olorun wifun Adamu pe. “Je ohungbogbo ninu ogba. Sugbon mase je eso imo rere ati ibi. Bi o ba je ninu re iwo yio ku.”

OLUWA Olorun si wipe, “Ko dara ki okunrin ki owa nikan. Emi yio se oluranlowo fun.” Olorun mu eiye ati eranko wa si odo Adamu. Adamu fi oruko fun gbogbo won. O gbodo ni laakaye lati se eyi. Sugbon laarin awon eiye ati eranko kosi eniti o to lati je iyawo fun Adamu.

Olorun fi orun ijika kun Adamu. Omu okan ninu iha re, Olorun da Obirin lati inu iha Adamu. Obirin ti Olorun da ni iyawo fun Adamu.

Olorun da ohun gbogbo ni ojo mefa. Olorun si bukun ojo keje osi pe ni ojo isimi. Ninu ogba edeni, Adamu ati Efa aya re ngbe ninu ayo nla, won ngboran si Olorun. Olorun je OLUWA won, olupese fun won ati ore won.

Opin

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Bibeli Fun Awon Omode

Bawo ni gbogbo rẹ ṣe bẹrẹ? Nibo ni a ti wa? Kini idi ti irora pupọ wa ni agbaye? Ṣe ireti eyikeyi wa? Njẹ aye wa lẹhin ikú? Wa awọn idahun bi o ti ka itan otitọ yii ti aiye.

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Bibeli fun Awọn ọmọde, Inc. fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://bibleforchildren.org/languages/yoruba/stories.php

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa