Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Kíni Ìfẹ́ Tòótọ́?Àpẹrẹ

What Is True Love?

Ọjọ́ 1 nínú 12

Ìpòǹgbẹ fún ìfẹ́



Ọkàn gbogbo wa ló ń pòǹgbẹ fún ìfẹ́ bí a kò tilẹ̀ mọ èyí. Bí ìgbà tí a ṣẹ̀dá wa láti máa ní ìfẹ́ ló ti rí. Ọlọ́run ni ìfẹ́. Ǹjẹ́ ó wùn ọ́ láti mọ ìfẹ́ Ọlọ́run òtítọ́? Àti wípé ṣé ìfẹ́ rẹ ni láti fẹ́ràn Rẹ̀ dénú dénú pẹ̀lú gbogbo ọkàn, èémí, èrò, àti ipá rẹ bí?



Àmọ́ kíni ìfẹ́ òtítọ́? Onírúurú ìtumọ̀ ni ọ̀rọ̀ yí ní. A lè sọ lóhùn kan wípé, "mo fẹ́ràn kọfí. Mo fẹ́ràn ọkọ tàbí aya mi. Mo fẹ́ràn Jésù." Báwo ni a ṣe lè mọ ìfẹ́ òtítọ́? Báwo ló ṣe rí? Báwo ní tií ṣeni? Ǹjẹ́ ó tilẹ̀ ṣe pàtàkì bí?



Ìfẹ́ òtítọ́ kọjá ìsọpútú lára ẹni, ìmọ̀lára, ìlépa, tàbí ẹ̀kọ́. Ìfẹ́ òtítọ́ jẹ́ ìlépa tó múná-dóko fún ìwà l'álàfíà ẹlòmíràn. Ìfẹ́ òtítọ́ tó ń mú kí ògo tọ sí Ọlọ́run ni èrèdí ìdásílẹ̀ àti ìwàláàyè ìjọ náà.



Àwọn mìíràn ma sọ wípé ìjíhìn rere ni ìlépa tó jà jù fún ìjọ Ọlọ́run: “Olórí ojúṣe ìjọ náà ni ìjèrè ọkàn gbogbo àgbáyé. Iṣẹ́ ìjọ Ọlọ́run ni ìjèrè ọkàn” (Oswald J. Smith).



Àwọn mìíràn ma sọ wípé ìjọsìn ni: “Ìjíhìn rere kọ́ni ìlépa ìjọ Ọlọ́run tó jà jù. Ìjọsìn ni. A fi ìjíhìn rere lọ́lẹ̀ nítorí ìjọsìn kùnà. Ìjọsìn ló gbé'gbá orókè, kìíṣe ìjíhìn rere, nítorí Ọlọ́run ṣe pàtàkì ju ènìyàn lọ. Ní àkókò tí ìgbà yí bá dópin, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù àwọn tí a ti gbàlà bá wólẹ̀ níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run, ìjíhìn rere ma dópin lákòókò yí. Kòṣeémàní fún ìgbà díẹ̀ ni. Àmọ́ ìjọsìn ma wà fún ayérayé” (John Piper).



Mo wá ń dáa ní àbá wípé ìfẹ́ ló jàjù àti wípé ìjíhìn rere àti ìjọsìn ṣúyọ látinú ìfẹ́ náà. Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ láti fẹ́ Òhun pẹ̀lú gbogbo ọkàn, ẹ̀mí, àti ipá wọn. Jésù tẹnu mọ́ èyí, wípé òfin tó nípọn jùlọ ni kí a fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run wa pẹ̀lú Gbogbo ọkàn wa, Gbogbo ẹ̀mí wá, àti Gbogbo ipá wa. Gbogbo túmọ̀ sí Gbogbo rẹ̀ pátápátá. Síwájú síi Ó sọ fún wa wípé gbogbo ènìyàn ni yóò mọ̀ wípé ọmọlẹ́yìn Rẹ̀ ni a jẹ́ nípasẹ̀ ìfẹ́ tí a fi hàn sí ọmọlàkejì wa. Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù wá ṣàlàyé nínú ìwé tó fi ṣọwọ́ sí àwọn ará Kọ́ríńtì wípé ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́ jẹ́ ìwà rere tí yóò ṣe wá ní àǹfààní fún ayérayé, àmọ́ èyí tó dára jù nínú mẹ́ta yìí ni ìfẹ́.


Nípasẹ̀ ǹkan tí Ọlọ́run, Jésù, àti Pọ́ọ̀lù fi yé wa, ìfẹ́ ló fẹ́ dàbí ìlépa tó jàjù fún àwa àti ìjọ Ọlọ́run.


Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

What Is True Love?

Gbogbo ènìyàn ló fẹ́ mọ̀ ohun ti ìfẹ́ tòótọ́ jẹ́. Sùgbọ́n ènìyàn péréte ló màá ń wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ìfẹ́. Ìfẹ́ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn àkòrí inú Bíbélì àti ìsúra tó ṣe pàtàkí jùlọ ní ìgbé-ayé Krìstìẹ́nì. Ẹ̀kọ́ ...

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ilé-iṣẹ́ ìránṣẹ́ Thistlebend fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: www.thistlebendministries.org

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa