Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Gbígbé Ìgbé Ayé Ọ̀tọ̀: Gbígba Ẹni Tí A Jẹ́Àpẹrẹ

Living Changed: Embracing Identity

Ọjọ́ 1 nínú 6

Yíyí Ìbánúsọ Wa Padá



Nígbà tí wọ́n bá ní kí o júwe ara rẹ, kí ni ohun tó máa ń wá sí ọ lọ́kàn? 



Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ìbánúsọ mi máa ń fihàn irú obìnrin tí Ọlọ́run dá mi láti jẹ́. Láìsí ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ láti yí ìbánúsọ mi padà, ìdáhùn mi lè rí báyìí: “Mo jẹ́ ẹni ọdún márùndínláàádọ́ta, ọlọ́mọ méjì tí kìí ọ̀dọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, tí irun rẹ̀ tií ń di ewú, àti ojú tó hun jọ láti fi hàn pé òótọ́ ni. Mo ti ṣègbéyàwó fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo máa ń pariwo jù. Dókítà mi sọ pé mo sanra jù. Mi ò lè mí dé lẹ̀ nígbàtí mo bá ń sáré, mo sì máa ń fẹ́ràn midinmíìdìn àti ẹ̀dà ọ̀dùnkún ju ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀ lọ. Mo jẹ́ àlùfáà nínú ṣọ́ọ̀ṣì mi, àmọ́ mi ò kúnjú ìwọ̀n rárá, mo sì ti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan nínú ìgbésí ayé mi tẹ́lẹ̀ tí kò lè Jẹ́kí iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi fa'kọyọ.” 



Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdáhùn yẹn lè ní í ṣe pẹ̀lú ipò ìdílé mi, bí mo ṣe sanra, ẹ̀yà mi, ọjọ́ orí mi, iṣẹ́ tí mò ń ṣe àti àwọn irọ́ tí ayé ń pa fún mi, kò sọ irú ẹni tí mo jẹ́ gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ làwọn nǹkan kan nípa mi, wọn kì í ṣe ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ. Wọ́n jẹ́ àwọn ohun tó ṣẹlẹ yyí mi ká, ṣùgbọ́n wọn kòsọ ẹnití mo jẹ́ gangan.



Òtítọ́ ni pé ọmọ Ọlọ́run ni mí, ṣáájú ohun gbogbo. Àkàndá ènìyàn ni mí tí a dá fún àfojúsùn kan. Mo jẹ́ iṣẹ́ ọnà kan tó fani mọ́ra, tí Ẹlẹ́dàá ayé àtọ̀run fi ọgbọ́n ṣe. Mo mọ èyí báyìí, àmọ́ ìyípadà láti ìdáhùn àkọ́kọ́ sí ìdáhùn kejì yìí kò wáyé láàárín òru kan. 



Nígbà tí mo kọ́kọ́ gbà ìpè iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn obìnrin, kò jọ pé èmi gan ṣe pàtàkì. Dídúró lórí pèpéle láti sọ fún àwọn obìnrin pé a dá wọn dáradára ní àwòrán Ọlọ́run jẹ́ ohun tó ṣòro gan-an fún mi nígbàtí èmi pàápàá kò ríibẹ́ẹ̀. Mo béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run pé kí Ó jẹ́ kí n rí ohun tí Òun rí nígbà tó bá wò mí, mo sì gbẹ́kẹ̀ lé E pé Ó lè yí èrò mi pa dà. 



Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí mo ti ń fi ìjọ̀wọ̀-araeni àti ìgbẹ́kẹ̀lé hàn, mo lè rí ara mi báyìí bí ẹni tó rẹwà. Kò sinmi lórí ohun tó o rí nínú dígí. Ó máa ń wá látinú àlàáfíà ọkàn àti rírí i pé kì í ṣàṣìṣe. Ó tó fún mi pé ó dá mi ó sì pè mí ní ẹwà.



Tá a bá gba ohun tí Ọlọ́run sọ pé a jẹ́, ó máa jẹ́ ká ní ìgboyà. Mí mọ̀ tá a mọ̀ pé Ọlọ́run dára pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tá a ní pé ó dá wa lọ́nà tó fẹ́ ni yóò fún wa ní ìyè. Tá a bá mọ bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó, ti Ó gbà wá bí ati rí, a ó túbọ̀ le ni nífẹ̀ẹ́ ara wa síi. A kò lè tètè yí ìbánúsọ wa pa dà, a kò sì lè dá ṣe é. A gbọ́dọ̀ bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. 



Ìgbésẹ̀:



Tí o bá ń jìjà gùdù láti mọ irú ẹni tó o jẹ́, bẹ Ọlọ́run kíÓfi hàn ọ bí Òunṣeríọ. Béèrè pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ àwọn irọ́ tí o ti gbà gbọ́ nípa ara rẹ kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi òtítọ́ Rẹ̀ rọ́pò. Yíò wà pẹ̀lú rẹ títí tí wàá fi rí ara rẹ̀ lẹ́ni tó yẹ, tó rẹwà, tó lè ṣe nǹkan, tí a sì leè fẹ́ràn. Lai fi àkókò tí mo ti ń tẹ̀ lé Jésù ṣe, tí ọ̀rọ̀ tí ò ń sọ nípa ara rẹ kò bá bá ohun tí Òun sọ nípa rẹ mu, o túmọ̀ sí pe iṣẹ́ ṣì wà láti ṣe. Máa tẹra mọ́ ṣíṣe bẹ́ẹ̀, kí o sì bẹ Ọlọ́run pé kí Ó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí o lè mọ ẹni tó o jẹ́ nínú Kristi. 


Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Living Changed: Embracing Identity

Pẹ̀lú onírúurú ohùn tí ó ńsọ fún wa irú ẹni tí a óò jẹ́, kò jẹ́ ìyàlẹ́nu pé à ún jìjàkadì irúfẹ́ ènìyàn tí à ń pe ara wa. Ọlọ́run Kò fẹ́ kí á fi iṣẹ́ òòjọ́, ipò ìgbéyàwó, tàbí àṣìṣe júwe ara wa. Ó ún fẹ́ kí èrò Rẹ̀ jẹ́ à...

More

A fé dúpé lówó àwọn Changed Women Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú sí, ẹjòwó ṣe ìbẹ̀wò sí: https://www.changedokc.com

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa