Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Ṣíṣe Okoòwò L'ọ́nà T'ẹ̀míÀpẹrẹ

Doing Business Supernaturally

Ọjọ́ 1 nínú 6

Irọ́ tí ó pín sí ọ̀nà méjì>

.

Mo tí gbà irọ́ gbọ́ fún ọdún méjìdínlógún tí ó síwájú nínú ìrìn àjò mi gẹgẹbi kristiẹni.


àgbáyéIrọ́ yi jẹ èyí tí ó wọ́pọ̀ láàrín àwọn Kristẹni àti pé bí ó bá jẹ́ onísòwò àfàìmọ̀ kí iwọ pápá máì já irú ìjàkadì bayi rí.


Mo tí gbàgbọ́ wípé iṣẹ àrà àti iṣẹ Ẹ̀mí pín sí ọ̀nà méjì. Ó sí mú mì láti máà ṣe ohun tí kò kún ojú òṣùwọ̀n nípa sísa ipá mi. Nínú ìṣòwò mi àti nínú ìjọ Ọlọrun pẹlu.


Jẹ kí ńṣe àlàyé........................


Nígbàtí mo dì ọmọlẹyìn Kristi ni ilé ẹkọ gíga, mo ní àgbékalẹ̀ nínú ọpọlọ mí bí ẹnipe àwọn Kristẹni tí ó kún ojú òṣùwọ̀n... ní àwọn tí ó mú iṣẹ ìgbàgbọ wọn ní ọ̀kúnkúndùn... àwọn tí ó fí gbogbo ìgbé ayé wọn ṣe iṣẹ ìránṣẹ́. Pàápàá jùlọ àwọn tí ó ní ìgbé ayé tí ó lókìkí, àwọn oníwàásù, àwọn tí o nṣe iṣẹ ìríjú tí "ó fí ohun gbogbo sílẹ fún Jésù nìkan". Kò sì sí ọkàn nínú ẹnikẹni nínú wọn tí ó yà sí ìdí òwò ṣiṣe bí ó tí rí lójú t'èmi.


Nitorina mo ní ìmọ̀lára bí ẹnití kò kún ojú òṣùwọ̀n. Àti pé mo ní èrò láti fí ètò ẹkọ gíga nínú ìmọ̀ ìṣòwò mi silẹ láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì. Mó ní ìmọ̀lára pé bí mo bá dúró nínú òwò síse èmi kò ní jẹ Kristẹni ní kíkún, nigba gbogbo, ẹnití ìpè rẹ̀ nínú ìjọ yíò jẹ́ láti joko nínú ìgbìmọ̀ ìnáwó tàbí láti kò owó jọ fún àwọn tí nṣiṣẹ́ ìríjú lójú méjèjì fún Ọlọrun. Àwọn tí ó ńfi gbogbo ọjọ ayé wọ́n nṣiṣẹ ìránṣẹ́.


Ṣugbọn mo kùnà láti mọ pé a mú mi wọ iṣẹ ìránṣẹ́ kíkún láti ọjọ tí mo tí dì ẹni ìgbàlà. Bẹẹ náà ní ìwọ gẹgẹ pẹlu


Mo sí tún kùnà láti mọ pé òwò ṣíṣe kò mú ìfàsẹ́hìn wà fún ìpè mi sínú iṣẹ ìránṣẹ́. Gbogbo ọnà ní á fí wà ní pípé gẹgẹbi iṣẹ àlùfáà kíkún.


Kòsí ìpínyà méjì mọ


Kòsí iyatọ láàrin iṣẹ Ẹ̀mí àti iṣẹ ara. Ohun gbogbo ní ó wà nípa tí Ẹ̀mí. Ìjọba Ọlọrun wà káàkiri lórí gbogbo ìgbé ayé wà níbikíbi, kii sì ṣe nínú ilé ìjọsìn nìkan ní ó wà. Àti pé àwa onísòwò ní ìbáṣepọ̀ tí ó l'ọ́rìnrìn tí ó sí gbòòrò pẹlu àwọn ènìyàn jù àlùfáà lọ. Ni àfikún àwọn àyè diẹ ṣí sílẹ̀ láti ṣe àfihàn ifẹ àti agbára Ọlọrun ní ọnà airotẹlẹ


Ó ṣe ìlérí pé Òun yíò wà pẹlú wa àti pé Ẹ̀mí Rẹ̀ yíò tọ́ wa sọnà sínú òtítọ gbogbo. Òwò ṣíṣe rẹ̀ kò mú àdinku bá ìlérí yí. Ìyẹn jẹ ìròyìn nla, àbí bẹkọ?


Ọlọrun nduro dè wà láti mú imọran àti òye Rẹ kí ó l'ojutu láti ọ̀run wá sí ayé kí á sí kọ́ àwọn ọnà Rẹ nípa ṣíṣe àfihàn ojutu sí àwọn ìṣòro àgbáyé. Ayé tí bajẹ ó sí ńkígbe fún ìdáhùn (wo iwe Rómù 8:19). Á ní àyè sí ìdáhùn.......... nipasẹ Ẹ̀mí Mimọ. Á ní láti ní ìrètí láti jẹ alágbékálẹ̀, olùdásílè, olùpílẹ̀sẹ̀ àti olùpilẹ̀rọ ojutu sí ìgbé ayé ẹdá ènìyàn.


Ohun tí Jésù ṣe àfihàn rẹ nínú ìwòsàn ara jẹ ọ̀kannáa pẹlu agbára láti ṣe ìyípòpadà òwò rẹ̀......... àti agbègbè..... àti orílẹ̀-èdè pẹlu.


Njẹ ó tí kọ ìpínyà iṣẹ ara àti tí Ẹ̀mí silẹ bí? Ṣe ó ṣetan láti dàpọ̀ mọ awọn tí ó fẹ mú ìfẹ ọ̀run wá sí ayé ní agbègbè ìṣòwò rẹ àti ìgbé ayé rẹ lóni?


Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Doing Business Supernaturally

Mo gba irọ́ kan gbọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Irọ́ yìí wọ́pọ̀ l'ágbo Krìstìẹ́nì. Mo gbàgbọ́ nínú ìyàtọ̀ láàrin ohun tí kò jẹ mọ́ ẹ̀sìn àti ohun-mímọ́. Èyí fà mí sẹ́hìn gidi. D'arapọ̀ mọ́ mi láti ṣe àgbéyẹ̀wò bi Ọlọ́run ṣe fẹ...

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ilé-iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Gateway fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ ṣ'àbẹ̀wò sí: http://dbs.godsbetterway.com/

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa