Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Ìràpadà Ìlépa-ỌkànÀpẹrẹ

Dreams Redeemed

Ọjọ́ 1 nínú 7

Ìràpadà Àwọn Àlá (Ọjọ́ 1)


N kò mọ̀ wípé mo lè di ọmọ ọdún mọkànlélógún lókè erùpẹ̀. Lẹ́yìn onírúurú ìlọ̀kulọ̀ ìbáṣepọ̀, ìfipábánilòpọ̀, àti gbígbé ní àdúgbò tí jàgídíjàgọn ti gbilẹ̀, ní ọmọ ọdún mẹ́tàlá mama mí fi mí sílẹ̀ ní àdúgbò tó kún fún àwọn ọmọ-gọ̀nfé, pẹ̀lú àbúrò mi ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ nígbà náà, láti gbọ́ bùkátà ara wa fún oṣù mẹ́ta gbáko. Ní àkókò náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí ní k'ọ́wọ̀ọ́ rìn pẹ̀lú ọmọkùnrin kan tó jù mí lọ tó sì ń pèsè oúnjẹ àti ìdáàbòbò fún wa. Kò pẹ́ẹ̀ ìyanijẹ àti àbùkù bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹyọ nínú ìbáṣepọ̀ náà, èyí tó padà mú mi yan iṣẹ́ alájòótà pẹ̀lú àwọn obìnrin agbélépawó láàyò. L'ọ̀rọ̀ kan, ọ̀rẹ́ kùnrin mi ní máa ńṣe ìdúnàdúrà pẹ̀lú àwọn oníbàárà bẹ́ẹ̀ni ayé mi ń kẹ̀ lọ lójú ẹ̀mí mi. 


Jésù Wọlé. 


Nínú Rẹ̀, ni mo ti rí ọrẹ ọ̀fẹ́, ìwòsàn, àti ipasẹ̀ tó lọ sí òmìnira. Àwọn àlá rere àti ìlépa mi bẹ̀rẹ̀ sí ní padà wá. Mo bẹ̀rẹ̀ sí ní ronú nípa ọjọ́ kan tí mo máa ní ilé tèmi, tí odi kékeré onígi funfun rọ̀gbà yi ká, àti pápá ọ̀dàn pẹ̀lú oríṣiríṣi ǹkan ìṣeré ọmọdé lóríi rẹ̀. Mo ní àfojúsùn àti ní ẹbí tó wà bíi òṣùṣù ọwọ̀ tí wọ́n sì ń jẹ́ orúkọ kan. Àlá mi dá lé ààbò àti ìdúróṣinṣin—èyí tí n kò ní àǹfààní láti jẹ̀gbádùn rẹ̀ nígbà èwe.


Mo ṣe àṣìṣe pẹ̀lú èrò wípé níwọ̀n ìgbà tí mo bá ń lọ sí Ilé ìjọsìn, tí mò ń ka àwọn ìwé tó dára, tí mo sì ńṣe ohun tó tọ́, gbogbo ìlépa mi ma wá sí ìmúṣẹ àti wípé Jésù ma lé gbogbo ìpèníjà ayé jìnà sí mi. 


Ní ọdún díẹ̀, ohun gbogbo bẹ̀rẹ̀ sí ní lọ gẹ́gẹ́bí ètò mi. A gbé mi níyàwó mo sì ní ọmọ tó rẹwà kan, a sì ń gbé ní ilé tó ní ọgbà. Ìgbésí ayé mi wá dùn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ sí ní jowú ara mi! 


Nígbà tí ó di mímọ̀ fún mi wípé ọkọ mì ń yan àlè, àti wípé kò ṣetán láti tiraka fún ìmúbọ̀sípò ìgbéyàwó wa, bíi wípé gbogbo ìrètí fún ayé mi ti dópin ló ṣe rí. Irúfẹ́ ìgbésí ayé tí mo tiraka láti ní ti wó palẹ̀. 


Nínú ewì rẹ̀ tí ó pè ní, “Harlem,” Langston Hughes bèrè ìbéèrè kan. “Kí ló ma ṣẹlẹ̀ sí àlá tó ní ìdádúró?”


 “Ṣé ó ma gbẹ dànù ni


      bíi èso àjàrà tí a fi sílẹ̀ sínú òrùn?


      Àbí ṣe ni yóò ta bí egbò—


      Tí yóò sì f'eré ge?”


Mo ní ìgbàgbọ́ wípé ibi tí àwọn àlá àti ìlépa wa bá yọrí sí nígbà tí wọ́n bá ní ìdádúró, tí ọwọ́ wa kò tó wọn, tàbí tí wọ́n wó palẹ̀, dá lóríi ẹni tó lá àlá náà. Ìhà tí a bá kọ ló máa fihàn bóyá a máa fà súnmọ́ ìpinnu Ọlọ́run fún ayé wa tàbí fà sẹ́yìn kúrò nínú rẹ̀.


Lẹ́yìn tí ọkọ mì jẹ́wọ́ ìkùnà rẹ̀, ó ní ìpinnu kan tó wá kojú mi…


Ibo ni mo wá fẹ́ fi ìrètí mi sí báyìí? Ṣé inú ìlépa tí mo ní fún ayé mi ni ìrètí mi ma wá wà báyìí? Àbí Ọlọ́run ni mo ma fi ṣe ìrètí?


Bí Bíbélì ti fi yé wa, ìrètí pípẹ́ a máa ṣ'ọkàn l'àárẹ̀, àmọ́ ìrètí nínú Jésù jẹ́ ìdákọ̀ró fún ọkàn wa. Kò ṣeé ṣe fún mi láti fagilé àwọn ǹkan tí mò ń làkọjá, bó tilẹ̀ wù mí kí èyí ṣeé ṣe, àmọ́ mo kàn ní àǹfààní láti yan ìhà tí mo máa kọ sí wọn. 


Mo fẹ́ kí o ṣe àṣàrò lórí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí: Ibo ni ìrètí rẹ wà lónìí? Ṣé inú ìlépa rẹ ni ìrètí rẹ wà bí? Àbí nínú Ẹni Náà tí ń Fúnni ní Àlá Rere ni o fi ìrètí rẹ pamọ́ sí? 


Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Dreams Redeemed

Kíni a lè ṣe nígbà tí àwọn ìlépa wa bá dàbí èyí tó jìnà réré tàbí bíi ìgbà tí a kò bá lè bá a láíláí? Lẹ́yìn tí mo borí ìlòkulò àti ìbanilọ́kànjẹ́, pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn ti ìkọ̀sílẹ̀, mo ti dojúkọ ìbéèrè yìí lẹ́ẹ̀kànsi. Bóyá ...

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Harmony Grillo (I Am A Treasure) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ lọ sí: http://harmonygrillo.com

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa