Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Wiwá ÀlàáfíàÀpẹrẹ

Finding Peace

Ọjọ́ 1 nínú 17

Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Gbogbo Ìfọ̀kànbalẹ̀



Kí a tó bẹ̀rẹ̀ ìpéjọpọ̀ kan ní àìpẹ́ yìí, èmi àti akẹgbẹ́ mi kan lọ jẹun ní ilé-oúnjẹ ìgbàlódé kan ní Èbúté Mẹ́ta. Nígbà tí ọ̀dọ́mọbìrin kan tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í to tábìlì, mo bèrè lọ́wọ́ rẹ̀: “Tí o bá ní àǹfààní láti bèrè ohun kan tí o fẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, kíni ǹkan to máa bèrè fún lọ́wọ́ Rẹ̀?”



Láì f'àkókò ṣòfò, ó dáhùn wípé: “Máa bèrè fún ìfọ̀kànbalẹ̀.”



Pẹ̀lú omijé lójú ni ó fi sọ fúnwa nípa màmá rẹ̀ àgbà tó di olóògbé lọ́jọ́ díẹ̀ sẹ́yìn.



Pẹ̀lú àlàyé tó ṣe fúnwa, ó wá sí òye mi wípé kò sí ẹnì kankan tó gba Ọlọ́run gbọ́ nínú ẹbí rẹ̀—láì yọ òhun fúnrarẹ̀ sílẹ̀. Ọmọbìnrin yìí kòfi taratara kọ Ọlọ́run sílẹ̀. Ohun kan tí ó mọ̀ ni wípé òhun kò ní ìsinmi ọkàn, kò tún wá mọ bí yóò ti yanjú àìní ìsinmi yìí, tàbí ohun tí ó fà á. Bíi ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí, ṣe ló kàn ń sùn tó sì ń jí, láì ní èrèdí kan pàtó fún ìgbésí ayéè rẹ̀.



Ọmọbìnrin yìí jé àpẹrẹ bí ọ̀pọ̀ tí ń gbé ayéè wọn lónìí—tí wọ́n kàn ń lọ káàkiri, pẹ̀lú ìgbìyànjú láti wá ǹkan jẹ, tí wọ́n sì ń sapá láti móríbọ́ ní gbogbo ọ̀nà.



Lọ́pọ̀ ìgbà, bíi wípé kò sí ọ̀nà àbáyọ tó yanjú kúrò nínú ìdàrúdàpọ̀ tí a wà ló máa ń rí—pàápàá nípa bó ti máa ṣe wá bíi wípé a kò jámọ́ ǹkankan, àti àìní ìfọ̀kànbalẹ̀. Síwájú si, bíi wípé kò sí ìdí tó jọjú fúnwa láti tẹ̀síwájú nínú ìlàkàkà ayéè wa.



Ọmọbìnrin tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ṣe àlàyé wípé, “òhun nílò ìfọ̀kànbalẹ̀.” Àwọn ẹlòmíràn ma sọ wípé, “Ṣeni mo ń dáwà.” Àwọn mìíràn má sọ wípé, “Kání aya/ọkọ mi fẹ́ràn mi bó ti yẹ ni, inú mi ò bá dùn.” Oríṣiríṣi ọ̀nà ṣùgbọ́n ǹkan ẹyọ kan ṣoṣo ni gbogbo wọn ń gbìyànjú láti sọ: “Ǹkan ò lọ bótiyẹ ... Inú mi kò dùn. Nkò ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Kíló rọ̀ lù mí gan?”



Ọ̀pọ̀ ló ti lu kúdẹ àwọn ìròyìn tó ń tàn ká ní ìgboro èyí tó dí wọn lọ́wọ́ láti rí Ọlọ́run bíi ojútùú sì ìṣòro wọn. Àwọn àṣà tó ń tọ̀nká ní ìgboro ni: “Tí ó bá lè dín ọ̀rá-ara rẹ kù, wọ irúfẹ́ aṣọ kan, wa ọkọ̀ bọ̀gìnì, gbé ní ilé tó gbówó lérí …” àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n kò sí ìkankan nínú àwọn ìdáhùn tí ati sọ ṣáájú tàbí àwọn irú rẹ̀ tí ènìyàn lè fúnwa tí yóò gbọ́ ǹkan tí à ń wá.



Ọmọbìnrin náà mọ ohun tí ó tọ́ láti wá: ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ní máa ń pòǹgbẹ síi—ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó sì lè ṣe àkàwé rẹ̀ bótiye ni ìfọ̀kànbalẹ̀.



Gẹ́gẹ́ bíi olùṣọ́-àgùntàn fún ọdún ọgọ́ta-ólé, mo lè fi dá ọ lójú wípé àyàfi tí ó bá ní ìfọ̀kànbalẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, o kò lè ní ìrírí àlàáfíà tópé ní Ìgbésí-ayé rẹ. 


Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Finding Peace

Se o túbò fé àlàáfíà ní ayé rè? Se o fé kí ìparóró wulèé ju ìfé okàn lo? O lè jèrè àlàáfíà tòótọ́ àmó láti orísun kan péré—Olórun. Dara pò mò Dr. Charles Stanley bí o ñ se fi ònà sí ìbàlè okàn tí ñ yí ayé ènì padà hàn e,...

More

A fé láti dúpé lówó Isé òjísé Touch fún ìpésé ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí, E jòó ṣèbẹ̀wò: https://intouch.cc/peace-yv

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa