Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Bí A Ṣe Lè Ka Bíbélì (Àwọn Ìpìlẹ̀)Àpẹrẹ

How To Study The Bible (Foundations)

Ọjọ́ 1 nínú 5

Ìdí tí kíkọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe ṣe pàtàkì


Kò ṣe é ṣe kí á mọ Ọlọ́run láì mọ Bíbélì.


Mo rántí ìgbà àkọ́kọ́ tí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí. Mo jẹ́ ọ̀dọ́ Kristẹni tí ó ní ìháragàgà láti yan ohun tí ó tọ́ láti tọ́ ọkàn-àyà mi sọ́nà sí àwọn ìfẹ́-ọkàn títọ́. Mo mọ̀ wípé Ọlọ́run le yí ayé mi padà mo sì fẹ́ mọ̀-Ọ́n tímọ́tímọ́.


Báwo ni ó ṣe rí? Kíni Ó fẹ́ láti ọ̀dọ̀ mi? Kíni ìdí tí mo fi wà níbí?


Ní ọdún mẹwàá síwájú, mo fi sí isẹ́ láti kọ́ Bíbélì bí mo ti lè kọ́ kí n le mọ Ọlọ́run jinlẹ̀. Ìpinnu náà ti mú mi lọ sí ọ̀nà tí èmi kò le rò rárá.


Ìfọkànsìn kúkúrú yìí jẹ́ ìfihàn sí díẹ̀ nínú àwọn òye tí ó wúlò jùlọ tí mo ní ní ọdún mẹwàá tí ó kọjá. Ìwọ yíò ṣe àwárí àwọn ọ̀nà, àwọn irinṣẹ́, àti àwọn ọgbọ́n láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti ní ànfààní púpọ̀ jùlọ nínú àkókò kíkà rẹ, bákan náà ìwúrí láti gbàgbọ́ pé mímọ Bíbélì rẹ tọ́ sí gbogbo iṣẹ́ tí o nílò nítorí èrè náà ni Ọlọ́run fúnra Rẹ̀.


Lo ìpèníjà náà kí o sì kọ́ bí o ṣe lè yí ìrírí Bíbélì rẹ padà láti iṣẹ́ lásán sí àṣà tí ó ṣe pàtàkì. Ọlọ́run ń retí rẹ kí o le mọ Òun síi. Ó ti fi ìpè nlá pè ọ́. Ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn nàá wà lọ́wọ́ rẹ.



Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

How To Study The Bible (Foundations)

Ó rọrùn láti rẹ̀wẹ̀sì, láti rò pé a kò múra tó, tàbí pé a kò ní ìtọ́sọ́nà ní ìgbà tí ó bá kan Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èrò mi ni láti mú ìlànà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rọrùn fún ọ ní àwọn ọ̀nà díẹ̀ nípa kíkọ́ ọ ní mẹ́ta nínú àwọn ìlànà tí...

More

A fẹ́ dúpẹ́ ní ọwọ́ Faithspring fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé sí iwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.fromhispresence.com

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa