Ọ̀fọ̀

Ọ̀fọ̀

Ọjọ́ 5

Ọ̀fọ̀ a máa ṣòro láti faradà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí onínúure ń fún ni ní àtìlẹyìn àti ìwúrí, a ní'mọ̀ lára nígbà míràn wípé kò sí ẹnìkan tó lòye ohun tí à ń là kọjá gan-an—bíi wípé àwa nìkan la wà nínú ìjìyà wa. Nínú ètò yìí, ìwọ yóò ka àwọn ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ tí yóò tù ọ́ nínú tí yóò sì ràn ẹ́ l'ọ́wọ́ láti ní òye ohun gbogbo pẹ̀lú ìrísí Ọlọ́run, láti ní ìmọ̀lára ìbákẹ́dùn nlá ti Olùgbàlà wa ní fún ọ, àti láti ní ìrírí ìdẹrùn kúrò nínú ìrora rẹ.

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Immersion Digital, ilé-iṣẹ́ tó ṣe àgbékalẹ̀ Glo Bible, fún àǹfààní láti ṣe àmúlò ètò kíkà tí ó ṣeé yí padà yí. O lè ṣe àgbékalẹ̀ ètò yí pẹ̀lú ìrọ̀rùn àti onírúurú rẹ̀ nípasẹ̀ Glo Bible. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí www.globible.com
Nípa Akéde

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa