Isa 1

1
1IRAN Isaiah ọmọ Amosi, ti o rí nipa Juda ati Jerusalemu li ọjọ Ussiah, Jotamu, Ahasi, ati Hesekiah, awọn ọba Juda.
OLUWA Bá Àwọn Eniyan Rẹ̀ Wí
2Gbọ́, ẹnyin ọrun, si fi eti silẹ, iwọ aiye: nitori Oluwa ti sọ̀rọ, emi ti bọ́, emi si ti tọ́ awọn ọmọ, nwọn si ti ṣọ̀tẹ si mi.
3Malũ mọ̀ oluwa rẹ̀, kẹtẹ́kẹtẹ si mọ̀ ibujẹ oluwa rẹ̀: ṣugbọn Israeli kò mọ̀, awọn enia mi kò ronu.
4A! orilẹ-ède ti o kún fun ẹ̀ṣẹ, enia ti ẹrù ẹ̀ṣẹ npa, irú awọn oluṣe buburu, awọn ọmọ ti iṣe olubajẹ: nwọn ti kọ̀ Oluwa silẹ, nwọn ti mu Ẹni-Mimọ́ Israeli binu, nwọn si ti yipada sẹhìn.
5Ẽṣe ti a o fi lù nyin si i mọ? ẹnyin o ma ṣọ̀tẹ siwaju ati siwaju: gbogbo ori li o ṣaisàn, gbogbo ọkàn li o si dakú.
6Lati atẹlẹ̀sẹ titi fi de ori kò si ilera ninu rẹ̀; bikòṣe ọgbẹ́, ipalara, ati õju ti nrà: nwọn kò iti pajumọ, bẹ̃ni a kò iti dì wọn, bẹ̃ni a kò si ti ifi ororo kùn wọn.
7Ilẹ nyin di ahoro, a fi iná kun ilu nyin: ilẹ nyin, alejo jẹ ẹ run li oju nyin, o si di ahoro, bi eyiti awọn alejo wó palẹ.
8Ọmọbinrin Sioni li a si fi silẹ bi agọ ninu ọgbà àjara, bi abule ninu ọgbà ẹ̀gúsí, bi ilu ti a dóti.
9Bikòṣe bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti fi iyokù diẹ kiun silẹ fun wa, awa iba ti dabi Sodomu, awa iba si ti dabi Gomorra.
10Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin olori Sodomu; fi eti si ofin Ọlọrun wa, ẹnyin enia Gomorra.
11Oluwa ni, kini ọ̀pọlọpọ ẹbọ nyin jasi fun mi? emi kún fun ọrẹ sisun agbò, ati fun ọrá ẹran abọ́pa; bẹ̃ni emi kò si ni inu didùn si ẹjẹ akọ malũ, tabi si ti ọdọ-agutan, tabi si ti obúkọ.
12Nigbati ẹnyin wá lati fi ara hàn niwaju mi, tali o bere eyi lọwọ nyin, lati tẹ̀ agbalá mi?
13Ẹ má mu ọrẹ asan wá mọ́: turari jasi ohun irira fun mi; oṣù titun ati ọjọ isimi, ìpe ajọ, emi kò le rọju gbà; ẹ̀ṣẹ ni, ani apèjọ ọ̀wọ nì.
14Oṣù titun nyin ati ajọ ìdasilẹ nyin, ọkàn mi korira; nwọn jasi iyọlẹnu fun mi; o sú mi lati gbà wọn.
15Nigbati ẹnyin si nà ọwọ́ nyin jade, emi o pa oju mi mọ fun nyin: nitõtọ, nigbati ẹnyin ba gbà adura pupọ, emi kì yio gbọ́: ọwọ́ nyin kún fun ẹ̀jẹ.
16Ẹ wẹ̀, ki ẹ mọ́; mu buburu iṣe nyin kuro niwaju oju mi: dawọ duro lati ṣe buburu;
17Kọ́ lati ṣe rere; wá idajọ, ràn awọn ẹniti a nilara lọwọ, ṣe idajọ alainibaba, gbà ẹjọ opó rò.
18Oluwa wipe, wá nisisiyi, ki ẹ si jẹ ki a sọ asọyé pọ̀: bi ẹ̀ṣẹ nyin ba ri bi òdodó, nwọn o si fun bi òjo-didì; bi nwọn pọ́n bi àlãri, nwọn o dabi irun-agutan.
19Bi ẹnyin ba fẹ́ ti ẹ si gbọran, ẹnyin o jẹ ire ilẹ na:
20Ṣugbọn bi ẹnyin ba kọ̀, ti ẹ si ṣọ̀tẹ, a o fi idà run nyin: nitori ẹnu Oluwa li o ti wi i.
Ìlú tí Ó kún fún Ẹ̀ṣẹ̀
21Ilu otitọ ha ti ṣe di àgbere! o ti kún fun idajọ ri; ododo ti gbe inu rẹ̀ ri; ṣugbọn nisisiyi, awọn apania.
22Fadaka rẹ ti di ìdarọ́, ọti-waini rẹ ti dà lu omi:
23Awọn ọmọ-alade rẹ di ọlọ̀tẹ, ati ẹgbẹ olè: olukuluku nfẹ́ ọrẹ, o si ntọ̀ erè lẹhin: nwọn kò ṣe idajọ alainibaba, bẹ̃ni ọ̀ran opó kò wá sọdọ wọn.
24Nitorina Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ẹni alagbara Israeli, wipe, A, emi o fi aiya balẹ niti awọn ọtá mi, emi o si gbẹ̀san lara awọn ọtá mi.
25Emi o yi ọwọ́ mi si ara rẹ, emi o si yọ́ ìdarọ́ rẹ kuro patapata, emi o si mu gbogbo tanganran rẹ kuro:
26Emi o si mu awọn onidajọ rẹ pada bi igbà iṣãju, ati awọn igbìmọ rẹ bi igbà akọbẹ̀rẹ: lẹhin na, a o pè ọ ni, Ilu ododo, ilu otitọ.
27Idajọ li a o fi rà Sioni pada, ati awọn ti o pada bọ̀ nipa ododo.
28Iparun awọn alarekọja pẹlu awọn ẹlẹṣẹ yio wà pọ̀, ati awọn ti o kọ̀ Oluwa silẹ li a o parun.
29Nitoriti oju yio tì wọn niti igi-nla ti ẹnyin ti fẹ, a o si dãmu nyin niti ọgbà ti ẹnyin ti yàn.
30Nitori ẹnyin o dabi igi-nla ti ewe rẹ̀ rọ, ati bi ọgbà ti kò ni omi.
31Alagbara yio si dabi ògùṣọ̀, iṣẹ rẹ̀ yio si dabi ẹta-iná, ati awọn mejeji yio jọ jona pọ̀, ẹnikẹni kì yio si pa wọn.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Isa 1: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa