I. Pet 2

2
Òkúta Ààyè ati Orílẹ̀-Èdè Mímọ́
1NITORINA ẹ fi arankàn gbogbo lelẹ li apakan, ati ẹ̀tan gbogbo, ati agabagebe, ati ilara, ati sisọ ọ̀rọ buburu gbogbo.
2Bi ọmọ-ọwọ titun, ki ẹ mã fẹ wàra ti Ẹmí na eyiti kò li ẹ̀tan, ki ẹnyin ki o le mã ti ipasẹ rẹ̀ dàgba si igbala,
3Bi ẹnyin ba ti tọ́ ọ wò pe, olõre li Oluwa:
4Ẹniti ẹnyin ntọ̀ bọ̀, bi si okuta ãye, ti a ti ọwọ́ enia kọ̀ silẹ nitõtọ, ṣugbọn lọdọ Ọlọrun, àṣayan, iyebiye,
5Ẹnyin pẹlu, bi okuta ãye, li a kọ ni ile ẹmí, alufa mimọ́, lati mã ru ẹbọ ẹmí, ti iṣe itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun nipa Jesu Kristi.
6Nitori o mbẹ ninu iwe-mimọ́ pe, Kiyesi i, Mo fi pàtaki okuta igunle, àṣayan, iyebiye, lelẹ ni Sioni: ẹniti o ba si gbà a gbọ́ oju kì yio ti i.
7Nitorina fun ẹnyin ti o gbagbọ́, ọla ni: ṣugbọn fun awọn ti kò gbagbọ́, okuta ti awọn ọmọle kọ̀ silẹ, on na li o di pàtaki igunle,
8Ati pẹlu, okuta idigbolu, on apata ikọsẹ̀. Nitori nwọn kọsẹ nipa ṣiṣe aigbọran si ọrọ na ninu eyiti a gbé yàn wọn si pẹlu.
9Ṣugbọn ẹnyin ni iran ti a yàn, olu-alufa, orilẹ-ède mimọ́, enia ọ̀tọ; ki ẹnyin ki o le fi ọla nla ẹniti o pè nyin jade kuro ninu òkunkun sinu imọlẹ iyanu rẹ̀ hàn:
10Ẹnyin ti kì iṣe enia nigbakan rí, ṣugbọn nisisiyi ẹnyin di enia Ọlọrun, ẹnyin ti kò ti ri ãnu gbà ri, ṣugbọn nisisiyi ẹ ti ri ãnu gbà.
Ẹ Jẹ́ Iranṣẹ Ọlọrun
11Olufẹ, mo bẹ̀ nyin, bi alejò ati bi èro, lati fà sẹhin kuro ninu ifẹkufẹ ara, ti mba ọkàn jagun;
12Ki ìwa nyin larin awọn Keferi kí o dara; pe, bi nwọn ti nsọ̀rọ nyin bi oluṣe buburu, nipa iṣẹ rere nyin, ti nwọn o mã kiyesi, ki nwọn ki o le mã yìn Ọlọrun logo li ọjọ ìbẹwo.
13Ẹ mã tẹriba fun gbogbo ìlana enia nitori ti Oluwa: ibãṣe fun ọba, bi fun olori;
14Tabi fun awọn bãlẹ, bi fun awọn ti a rán lati ọdọ rẹ̀ fun igbẹsan lara awọn ti nṣe buburu, ati fun iyìn awọn ti nṣe rere.
15Bẹ̃ sá ni ifẹ Ọlọrun, pe ni rere iṣe, ki ẹ le dá òpe awọn wère enia lẹkun:
16Bi omnira, laisi lo omnira nyin fun ohun bibo arakàn nyin mọlẹ, ṣugbọn bi ẹrú Ọlọrun.
17Ẹ bọ̀wọ fun gbogbo enia. Ẹ fẹ awọn ará. Ẹ bẹru Ọlọrun. Ẹ bọ̀wọ fun ọba.
Àpẹẹrẹ Ìjìyà Jesu
18Ẹnyin ọmọ-ọ̀dọ, ẹ mã tẹriba fun awọn oluwa nyin pẹlu ìbẹru gbogbo; ki iṣe fun awọn ẹni rere ati oniwa tutu nikan, ṣugbọn fun awọn onrorò pẹlu.
19Nitoripe eyi ni ìtẹwọgba, bi enia ba fi ori tì ibanujẹ, ti o si njìya laitọ́, nitori ọkàn rere si Ọlọrun.
20Nitori ogo kili o jẹ, nigbati ẹ ba ṣẹ̀ ti a si lù nyin, bi ẹ ba fi sũru gbà a? ṣugbọn nigbati ẹnyin ba nṣe rere; ti ẹ si njiya, bi ẹnyin ba fi sũru gbà a, eyi ni itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun.
21Nitori inu eyi li a pè nyin si: nitori Kristi pẹlu jìya fun nyin, o fi apẹrẹ silẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã tọ̀ ipasẹ rẹ̀:
22Ẹniti kò dẹṣẹ̀, bẹni a kò si ri arekereke lì ẹnu rẹ̀:
23Ẹni, nigbati a kẹgan rẹ̀, ti kò si pada kẹgan; nigbati o jìya, ti kò si kilọ; ṣugbọn o fi ọ̀ran rẹ̀ le ẹniti nṣe idajọ ododo lọwọ:
24Ẹniti on tikararẹ̀ fi ara rẹ̀ rù ẹ̀ṣẹ wa lori igi, pe ki awa ki o le di okú si ẹ̀ṣẹ ki a si di ãye si ododo: nipa ìnà ẹniti a mu nyin larada.
25Nitori ẹnyin ti nṣako lọ bi agutan, ṣugbọn nisisiyi ẹnyin pada si ọdọ Oluṣọ-agutan ati Biṣopu ọkàn nyin.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Pet 2: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa